Oluwa mi mo
njade lo
1. Oluwa mi mo
njade lo
Lati se ise
ojo mi
Iwo nikan l'
emi o mo
L'oro l'
ero, ati n' ise
2. Ise t'o yan
mi l' anu re
Je ki nle se
tayotayo
Ki nr' oju
Re ni ise mi
K' emi si le
f' ife Re han
3. Dabobo mi
lowo 'danwo
K' o pa okan
mi mo kuro
L' owo
aniyan aiye yi
Ati gbogbo
ifekufe
4. Iwo t'oju Re
r' okan mi
Ma wa low'
otun mi titi
Ki nma sise
lo l'ase Re
Ki nf' ise
mi gbogbo fun O
5. Je ki nreru
Re t'o fuye
Ki nma sora
nigbagbogbo
Ki nma f'
oju si nkan t'orun
Ki nsi mura
d'ojo ogo
6. Ohunkohun t'
o fi fun mi
Je ki nle lo
fun ogo Re
Ki nfayo
sure ije mi
Ki mba O rin
titi d' orun
No comments:
Post a Comment