Monday, January 18, 2016

OLUWA mbo; ayé o mi,

OLUWA mbo; ayé o mi,
Oke y'o sidi n'ipo won,
At' irawo oju orun,
Y'o mu imole won kuro.

Oluwa mbo; bakan naa ko,
Bi o ti wa n'irele ri;
odo-aguntan ti a pa,
eni-iya ti o si ku.

Oluwa mbo; ni eru nla,
L'owo ina pelu ija,
L'or' iye apa Kérúbù,
Mbo, Onidajo arayé.

Eyi ha ni eni ti n rin,
Bi ero l'opopo ayé?
Ti a se 'nunibini i?
A! eni ti a pa l'eyi?

Ika: b'e wo 'nu apata,
B'e wo 'nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t'o segun
Y'o korin pe, Oluwa de.


AMIN

L'oju ale, 'gbat 'orun wo,

L'oju ale, 'gbat 'orun wo,
Won gbe abirun w'odo Re;
Onirum ni aisan won,
Sugbon won fayo lo 'Ie won

Jesu a de I‘ojo ale yi,
A sunmo, t'awa t`arun wa,
Bi a ko tile le ri O,
Sugbon a mo p'O sunmo wa.

Olugbala, wo osi wa;
Omi ko san, mi banuje,
Omi ko ni ife si O,
Ife elomi si tutu.

Omi mo pe, l.sa.n l'aye
Beni won K0 faye sile,
Omi l'ore tfko se‘re,
Beni won ko ii O sore.

Ko s'okan ninu wa t'o pe,
Gbogbo WI' il ni elese;
Awon t'o ii min O toto,
Mo ara Won ni alaipe.

Sugbon Jesu Olugbala
Eni bi awa n'lwo 'se,
‘Wo ti ri 'dnnwo bi awa
'Wo si ti mo ailera wa.

Agbar' owo Re wa sibe
Ore Re si li agbara
Gbo adurl ale wa yi,
Ni anu, wo gbogbo wa san.
       
Amin.

Baba, a tun pade l'oko Jesu

Baba, a tun pade l'oko Jesu
A si wa teriba lab'ese Re
A tun fe gb‘ohun wa soke si O
Lati Wa anu, lati korin 'yin.

Ayin O fun itoju ‘gbagbogbo,
Ojojumo l‘ao ma rohin ‘sc re;
Wiwa laye wa, anu Re ha ko?
Apa Re ki 0 fi ngba ni mera?

O se! Ako ye fun ife nla Re,
A sako kuro lodo Re poju;
Sugbon kikankikan ni O si np
Nje a de, a pada wa ‘le, Baba.

Nipa oko t‘0 bor'ohun gbogbo
Nipa ife t'o ta 'fe gbogbo yo,
Nipa eje ti a ta fun ese,
Silekun anu si gbani si ‘le.
   
Amin.

Nigba kan ni Betlehemu

Nigba kan ni Betlehemu
Ile kekere kan wa
Nib'i'ya kan te mo're si
Lori ibuje eran
Maria n'iya omo na
Jesu Kristi l'omo na

O t'orun wa s'ode aye
On l'Olorun Oluwa
O f'ile eran se ile
'Buje eran fun 'busun
Lodo awon otosi
Ni Jesu gbe li aye

Ni gbogbo igba ewe Re
O ngboran o si mb'ola
O feran Osi nteriba
Fun iya ti ntoju Re!
Oye ki gbogbo' omode
K'o se olugboran be

'Tori on je awose wa
A ma dagba bi awa
O kere ko le da nkan se
A ma sokun bi awa
O si le ba wa daro
O le ba wa yo pelu

A o foju wa ri nikehin
Ni agbara ife re
Nitori omo rere yi
Ni Oluwa wa l'orun
O nto awa omo re
S'ona ibiti On lo

Ki se ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L'awa o ri; sugbon lorun
Lowo otun 'Olorun
'Gba 'won 'mo Re b'irawo
Ba wa n'nu aso la


AMIN

B'olorun Oba orun

B'olorun Oba orun
Ti ma nsoro n'igba ni;
Otun ba wa soro be loni
Arakunrin, oto ni
Ohun t'Oba wi fun o;
Ohun kan l'aigbodo-mase;gboran.

CHORUS
Sa gboran, sa gboran;
Eyi ni 'fe Re
"Gbat'O ba ranse si o
Ohun kan ni ki o se
Sa gboran, sa gboran.


Bi o ba je t'Oluwa
O ni lati gbo tire,
Ko s'ona 'hinrere miran mo;
Mase sa ase Re ti
Ma si se lo oro re
'Gbat'Olugbala ba nsoro, sa gbo


Sa gboran, sa gboran;
Eyi ni 'fe Re
"Gbat'O ba ranse si o
Ohun kan ni ki o se
Sa gboran, sa gboran.


Bi o ba fe ni ipin
Ni'lu daradara ni
Leyin aye wa buburu yi;
Bi o ko tile m'ona


Sa gboran, sa gboran;
Eyi ni 'fe Re
"Gbat'O ba ranse si o
Ohun kan ni ki o se
Sa gboran, sa gboran.
Krist y'o wipe, "Tele Mi"
Igbagbo yo si wipe, "sa gboran"

Sunday, January 17, 2016

OLUWA mi, mo n jade lọ - Forth in Thy Name, O Lord, I go

OLUWA mi, mo n jade lọ,
Lati se isẹ ojọ mi,
Iwọ nikan l'emi o mọ,
L'ọrọ, l'ero, ati n'ise.

Isẹ t'o yan mi l'anu RẸ,
Jẹ ki n le se tayọtayọ;
Ki n roju Rẹ ni isẹ mi,
K'emi si le f'ifẹ Rẹ han.

Dabobo mi lọwọ 'danwo,
K'o pa ọkan mi mọ kuro,
L'ọwọ aniyan aye yi,
Ati gbogbo ifẹkufẹ.

Iwọ t'oju Rẹ r'ọkan mi,
Ma wa lọw' ọtun mi titi;
Ki n ma sisẹ lọ lasẹ Rẹ,
Ki n f'isẹ mi gbogbo fun Ọ.

Jẹ ki n r'ẹru Rẹ t'o fuyẹ,
Ki n ma sọra nigba gbogbo;
Ki n ma f'oju si nkan t'ọrun,
Ki n si mura d'ọjọ ogo.

Ohunkohun t'o fi fun mi,
Jẹ ki n le lo fun ogo Rẹ;
Ki n f'ayọ sure ije mi,
Ki n ba Ọ rin titi d'ọrun.


AMIN




1 Forth in Thy Name, O Lord, I go,
My daily labor to pursue;
Thee, only Thee, resolved to know
In all I think, or speak, or do.

2 The task Thy wisdom hath assigned
O let me cheerfully fulfill;
In all my works Thy presence find,
And prove Thy good and perfect will.

3 Thee may I set at my right hand,
Whose eyes mine inmost substance see,
And labor on at Thy command,
And offer all my works to Thee.

4 Give me to bear Thy easy yoke,
And every moment watch and pray;
And still to things eternal look,
And hasten to Thy glorious day:

5 Fain would I still for Thee employ
Whate'er Thy bounteous grace hath given,
And run my course with even joy,
And closely walk with Thee to Heaven.

WA s'adura oorọ,

WA s'adura oorọ,
Kunlẹ k'a gbadura;
Adura ni ọpa Kristiani,
Lati b'Ọlọrun rin.

Lọsan, wolẹ labẹ,
Apat' ayeraye;
 Itura ojiji Rẹ dun,
Nigba t'orun ba mu.

Jẹ ki gbogbo ile,
Wa gbadura l'alẹ;
Ki ile wa di t'Ọlọrun,
Ati 'bode ọrun.

Nigba ti o d'ọganjọ,
Jẹ k'a wi l'ẹmi, pe,
Mo sun, sugbọn ọkan mi ji
Lati ba Ọ sọna.
         
AMIN