Sunday, January 17, 2016

Gbat' agbara Olorun de

Gbat' agbara Olorun de
Li ojo Pentikosti
Sa ifoju sona pari
Tori won ri Emi gba

Chorus
Ran agbara Oluwa
Ran agbara Oluwa
Ran agbara Oluwa
Ki o si baptis wa

Ela 'han ina be le won
Won si wasu oro na
Opolopo enia gbagbo
Won yi pada s' Olorun
Ran agbara Oluwa

A nwona fun Emi Mimo
Gbogbo wa f'ohun sokan
Mu 'leri na se Oluwa
Ti a se nin'oro Re
Ran agara Oluwa

Jo fi agbara Re kun wa
Fun wa ni 'bukun t'a nfe
Fi ogo Re kun oka wa
B'a ti nfi' bagbo bebe
Ran agbara Oluwa


AMIN

4 comments: