Sunday, January 17, 2016

Elese; mo n fe ‘bukun;

Elese; mo n fe ‘bukun;
Onde: mo n fe d’omnira;
Alare: mo n fe ‘sinmi,
“Olorun, saanu fun mi”.

Ire kan emi ko ni,
ese sa l’o yi mi ka,
Eyi nikan l’ebe mi,
“Olorun, saanu fun mi”.

Irobinuje oka               
Nko gbodo gboju s’oke;
Iwo sa mo edun mi;
“Olorun, saanu fun mi”.

okan ese mi yi n fe,
Sa wa sinmi laya Re;
Lat’ oni, mo di Tire,
“Olorun, saanu fun mi”.

Enikan mbe l’or’ ite,
Ninu Re nikansoso,
N’ ireti at’ebe mi;
“Olorun, saanu fun mi”.

Oun o gba oran mi ro,
Oun ni Alagbawi mi;
Nitori Tire nikan;
“Olorun, saanu fun mi”.

2 comments: