ORE-OFE! ohun
Adun ni l'eti wa,
Gbohun-gbohun re
y'o gba orun kan,
Ayé o gbe pelu.
Ore-ofe sa,
N'igbekele mi;
Jesu ku fun arayé,
O ku fun mi pelu.
Ore-ofe l'o ko,
Oruko mi l'orun;
L'o fi mi fun od'-aguntan,
T'o gba iya mi je.
Ore-ofe to mi,
S'ona alafia;
O n toju mi lojojumo,
Ni irin ajo mi
Ore-ofe ko mi,
Bi a ti n'gbadura,
O pa mi mo titi d'oni,
Ko si je ki n sako.
Je k'ore-ofe yi,
F'agbara f'okan mi;
Ki n le fi gbogbo ipa mi,
At'ojo mi fun o.
Amin.
No comments:
Post a Comment