Monday, January 18, 2016

Nigba kan ni Betlehemu

Nigba kan ni Betlehemu
Ile kekere kan wa
Nib'i'ya kan te mo're si
Lori ibuje eran
Maria n'iya omo na
Jesu Kristi l'omo na

O t'orun wa s'ode aye
On l'Olorun Oluwa
O f'ile eran se ile
'Buje eran fun 'busun
Lodo awon otosi
Ni Jesu gbe li aye

Ni gbogbo igba ewe Re
O ngboran o si mb'ola
O feran Osi nteriba
Fun iya ti ntoju Re!
Oye ki gbogbo' omode
K'o se olugboran be

'Tori on je awose wa
A ma dagba bi awa
O kere ko le da nkan se
A ma sokun bi awa
O si le ba wa daro
O le ba wa yo pelu

A o foju wa ri nikehin
Ni agbara ife re
Nitori omo rere yi
Ni Oluwa wa l'orun
O nto awa omo re
S'ona ibiti On lo

Ki se ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L'awa o ri; sugbon lorun
Lowo otun 'Olorun
'Gba 'won 'mo Re b'irawo
Ba wa n'nu aso la


AMIN

1 comment:

  1. Top 10 Casinos in Columbus, OH (HOTEL) - Mapyro
    Find Casinos Near Me Near Me Near Me · MGM Resorts World Catskills 대전광역 출장샵 Casino · Harrah's 문경 출장샵 Cherokee 광주 출장샵 Casino Resort · Golden 광명 출장안마 Nugget 거제 출장마사지 Casino · Hard Rock Hotel & Casino

    ReplyDelete