Kii se l'ainireti,
Ni mo to wa;
Kii se l'aini 'gbagbo,
Ni mo kunle;
Ese ti gori mi,
Eyi sa l'ebe mi,
Eyi sa l'ebe mi
Jesu ti ku.
A! ese mi po ju,
O pon koko
Adale, adale,
Ni mo n d'ese
Ese aiferan Re,
Ese aigba O gbo,
Ese aigba O gbo,
Ese nlanla!
Oluwa mo jewo
Ese nla mi;
O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;
Jo, we ese mi nu!
K' okan mi mo loni,
K'okan mi mo loni,
Ki n di mimo.
Olododo ni o,
O n dariji;
L'ese agbelebu,
Ni mo wole;
Je k'eje iwenu,
Eje odagutan
Eje Odagutan,
We okan mi.
Gba naa, alafia,
Y'o d'okan mi;
Gba naa, n o ba O rin,
Ore airi;
Em' o f'ara ti O,
Jo ma to mi s'ona
Jo ma t? mi s'ona
Titi aiye.
No comments:
Post a Comment