Sunday, January 17, 2016

Yika or'ite Olorun,

Yika or'ite Olorun,
Egberun ewe wa;
Ewe t'a dari ese ji,
AwOn egbe mimo;

Chorus
N korin ogo, ogo, ogo.
N korin ogo, ogo, ogo

Wo! olukuluku won wo,
Aso ala mimo;
Ninu imole ailopin,
At'ayo ti ki sa,
N korin ogo, ogo, ogo.

Ki l'o mu won de ayé na,
Orun t'o se mimo,
Nib' alafia at'ayo,
Bi won ti se de 'be?
N korin ogo, ogo, ogo.

Nitori Jesu ta 'je Re,
Lati k'ese won lo;
A ri won ninu eje na,
Won di mimo laulau;
N korin ogo, ogo, ogo.

L'ayé, won wa Olugbala,
Won fe oruko Re;
Nisinsin yi won r'oju Re,
Won wa niwaju Re;
N korin ogo, ogo, ogo.

Orisun na ha n san loni?
Jesu, mu wa de 'be;
K'a le ri awon mimo na,
K'a si ba won yin O,
N korin ogo, ogo, ogo.


No comments:

Post a Comment