Sunday, January 17, 2016

OLUWA mbo; ayé o mi,

OLUWA mbo; ayé o mi,
Oke y'o sidi n'ipo won,
At' irawo oju orun,
Y'o mu imole won kuro.

Oluwa mbo; bakan naa ko,
Bi o ti wa n'irele ri;
odo-aguntan ti a pa,
eni-iya ti o si ku.

Oluwa mbo; ni eru nla,
L'owo ina pelu ija,
L'or' iye apa Kérúbù,
Mbo, Onidajo arayé.

Eyi ha ni eni ti n rin,
Bi ero l'opopo ayé?
Ti a se 'nunibini i?
A! eni ti a pa l'eyi?

Ika: b'e wo 'nu apata,
B'e wo 'nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t'o segun
Y'o korin pe, Oluwa de.

No comments:

Post a Comment