BABA mi gbọ temi!
'Wọ ni Alabo mi,
Ma sunmọ mi titi;
Oninure julọ!
Jesu Oluwa mi,
Iye at'ogo mi,
K'igba naa yara de,
Ti n ó de ọdọ Rẹ.
Olutunu julọ,
'Wọ ti n gbe inu mi,
'Wọ to mọ aini mi,
Fa mi, k'o si gba mi.
Mimọ, mimọ, mimọ,
Ma fi mi silẹ lai,
Se mi n'ibugbe Rẹ,
Tirẹ nikan lailai.
AMIN
No comments:
Post a Comment