Sunday, January 17, 2016

Bi Krist'ti da okan ni nde

Bi Krist'ti da okan ni nde
Aye mi ti dabi orun,
Larin 'banuje at'aro
Ayo ni lati mo Jesu,

Aleluya! Ayo l'o je

Pe, mo ti ri 'dariji gba.
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s'ewu, Jesu wa nibe.

Moti ro pe orun jinna

Sugbon nigbati Jesu de
L'orun ti de 'nu okan mi,
Nibe ni y'o si wa titi.

Nibo l'a le gbe I'aye

L'o r'oke tabi petele
L'ahere tabi agbala,
Ko s'ewu, Jesu wa nibe.

AMIN

2 comments: