Baba, Eleda wa,
Gbo orin iyin wa
L’aiye ati l’orun,
Baba Olubukun:
Iwo l’ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.
‘Wo Olorun Omo,
T’O ku lati gba wa;
Enit’O ji dide,
Ti O goke lo;
Iwo l’ogo, ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.
Si O Emi Mimo,
Ni a korin iyin:
Iwo t’o f’imole
Iye si okan wa;
Iwo l’ogo, ati iyin,
Ope ati ola ye fun.
Mimo, mimo, mimo,
N’iyin Metalokan:
L’aiye ati l’orun,
L’a o ma korin pe,
Iwo l’ogo, ati iyin,
Ope ati ola ye fun.
Amin.
No comments:
Post a Comment