Sunday, January 17, 2016

Kii se l'ainireti,

Kii se l'ainireti,
Ni mo to wa;
Kii se l'aini 'gbagbo,
Ni mo kunle;

Ese ti gori mi,
Eyi sa l'ebe mi,
Eyi sa l'ebe mi
Jesu ti ku.

A! ese mi po ju,
O pon koko
Adale, adale,
Ni mo n d'ese
  
Ese aiferan Re,
Ese aigba O gbo,
Ese aigba O gbo,
Ese nlanla!

Oluwa mo jewo
Ese nla mi;
O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;

Jo, we ese mi nu!
K' okan mi mo loni,
K'okan mi mo loni,
Ki n di mimo.

Olododo ni o,
O n dariji;
L'ese agbelebu,
Ni mo wole;

Je k'eje iwenu,
Eje odagutan
Eje Odagutan,
We okan mi.

Gba naa, alafia,
Y'o d'okan mi;
Gba naa, n o ba O rin,
Ore airi;

Em' o f'ara ti O,
Jo ma to mi s'ona
Jo ma t? mi s'ona
Titi aiye.

Apata ayeraye

Apata ayeraye
Se ibi isadi mi;
Je ki omi oun eje,
T'o n san lati iha Re,
Se iwosan f'ese mi,
K'o si so mi di mimo.

K' Ise ise owo mi,
Lo le mu ofin Re se;
B' itara mi ko l'are,
T' omije mi n san titi;
Won ko to fun etutu,
'Wo nikan l'o le gbala.

Ko s'ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa, k'o d'aso bo mi,
Mo n wo o fun iranwo;
Mo wa sib' orisun ni,
We mi, Olugbala mi.

'Gbati emi mi ba n lo,
T'iku ba p'oju mi de,
Ti mba n lo s'aye aimo,
Ti n ri o n'ite 'dajo;
Apata ayeraye,
Se ibi isadi mi.




1. Rock of Ages, cleft for me,
Let me hide myself in Thee;
Let the water and the blood,
From Thy wounded side which flowed,
Be of sin the double cure;
Save from wrath and make me pure.

2. Not the labor of my hands
Can fulfill Thy law’s demands;
Could my zeal no respite know,
Could my tears forever flow,
All for sin could not atone;
Thou must save, and Thou alone.

3. Nothing in my hand I bring,
Simply to the cross I cling;
Naked, come to Thee for dress;
Helpless look to Thee for grace;
Foul, I to the fountain fly;
Wash me, Savior, or I die.

4. While I draw this fleeting breath,
When mine eyes shall close in death,
[originally When my eye-strings break in death]
When I soar to worlds unknown,
See Thee on Thy judgment throne,
Rock of Ages, cleft for me,
Let me hide myself in Thee.




MA gesin lo l'ola nla Re;

MA gesin lo l'ola nla Re;
Gbo gbogb'ayé, n ke “Hosanna”
Olugbala, ma lo pele,
Lori im'ope at'aso.

Ma gesin lo l'ola nla Re;
Ma f'irele gesin lo ku;
Kristi, segun Re bere na;
Lori ese ati iku.

Ma gesin lo l'ola nla Re;
Ogun Angeli lat'orun;
N f'iyanu pelu ikanu,
Wo ebo to sunmole yi.

Ma gesin lo l'olanla Re;
Ija ikehin na de tan;
Baba, lor'ite Re l'orun,
N reti ayanfe omo Re.

Ma gesin lo l'olanla Re;
Ma f'irele gesin lo ku;
F'ara da irora f'eda;
Lehin na, n de k'O ma joba

ORE-OFE! ohun

ORE-OFE! ohun
Adun ni l'eti  wa,
Gbohun-gbohun re 
y'o gba orun kan,
Ayé o gbe pelu.
         
Ore-ofe sa,
N'igbekele mi;
Jesu ku fun arayé,
O ku fun mi pelu.

Ore-ofe l'o ko,
Oruko mi l'orun;
L'o fi mi fun od'-aguntan,
T'o gba iya mi je.
         
Ore-ofe to mi,
S'ona alafia;
O n toju mi lojojumo,
Ni irin ajo mi
         
Ore-ofe ko mi,
Bi a ti n'gbadura,
O pa mi mo titi d'oni,
Ko si je ki n sako.

Je k'ore-ofe yi,
F'agbara f'okan mi;
Ki n le fi gbogbo ipa mi,
At'ojo mi fun o. 

Amin.

Kristi, Oluwa ji loni, Halleluya

Kristi, Oluwa ji loni, Halleluya
Eda at” Angeli  nwi Ha!
Gb”ayo at”isegun ga-Ha!
Korun at” aye gberin – Ha!

Ise ti idande tan; Ha!
O jija, o ti segun; Ha!
Wo, sisu orun koja-Ha!
Ko wo sinu eje mo-Ha!
Lasan n'Iso at'ami'Hal
Kris woo run apadi; hal
Lasan l'agbara iku –hal
Kristi si paradise-Hal
O tun wa, Oba ogo, Hal
“iku itani re da?” Hal
Lekan l'O  ku, k'o gba wa, Hal
“Boji, isegun re da,? Hal

AMIN 

Gbat' agbara Olorun de

Gbat' agbara Olorun de
Li ojo Pentikosti
Sa ifoju sona pari
Tori won ri Emi gba

Chorus
Ran agbara Oluwa
Ran agbara Oluwa
Ran agbara Oluwa
Ki o si baptis wa

Ela 'han ina be le won
Won si wasu oro na
Opolopo enia gbagbo
Won yi pada s' Olorun
Ran agbara Oluwa

A nwona fun Emi Mimo
Gbogbo wa f'ohun sokan
Mu 'leri na se Oluwa
Ti a se nin'oro Re
Ran agara Oluwa

Jo fi agbara Re kun wa
Fun wa ni 'bukun t'a nfe
Fi ogo Re kun oka wa
B'a ti nfi' bagbo bebe
Ran agbara Oluwa


AMIN

OLUWA mbo; ayé o mi,

OLUWA mbo; ayé o mi,
Oke y'o sidi n'ipo won,
At' irawo oju orun,
Y'o mu imole won kuro.

Oluwa mbo; bakan naa ko,
Bi o ti wa n'irele ri;
odo-aguntan ti a pa,
eni-iya ti o si ku.

Oluwa mbo; ni eru nla,
L'owo ina pelu ija,
L'or' iye apa Kérúbù,
Mbo, Onidajo arayé.

Eyi ha ni eni ti n rin,
Bi ero l'opopo ayé?
Ti a se 'nunibini i?
A! eni ti a pa l'eyi?

Ika: b'e wo 'nu apata,
B'e wo 'nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t'o segun
Y'o korin pe, Oluwa de.