Saturday, March 28, 2015

Oluwa mi mo njade lo

Oluwa mi mo njade lo

1. Oluwa mi mo njade lo
Lati se ise ojo mi
Iwo nikan l' emi o mo
L'oro l' ero, ati n' ise

2. Ise t'o yan mi l' anu re
Je ki nle se tayotayo
Ki nr' oju Re ni ise mi
K' emi si le f' ife Re han

3. Dabobo mi lowo 'danwo
K' o pa okan mi mo kuro
L' owo aniyan aiye yi
Ati gbogbo ifekufe

4. Iwo t'oju Re r' okan mi
Ma wa low' otun mi titi
Ki nma sise lo l'ase Re
Ki nf' ise mi gbogbo fun O

5. Je ki nreru Re t'o fuye
Ki nma sora nigbagbogbo
Ki nma f' oju si nkan t'orun
Ki nsi mura d'ojo ogo

6. Ohunkohun t' o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki nfayo sure ije mi

Ki mba O rin titi d' orun

L’ oju ale gbat’ orun wo

L’ oju ale gbat’ orun wo

1. L’ oju ale gbat’ orun wo
Nwon gbe abirun w’ odo Re
Oniruru ni aisan won
Sugbon nwon f’ ayo lo ‘le won

2. Jesu a de l’ oj’ ale yi
A sunmo t’ awa t’ arun wa
Bi a ko tile le ri O
Sugbon a mo p’ O sunmo wa

3. Olugbala wo osi wa
Omi ko san mi banuje
Omi ko ni ife si O
Ife elomi si tutu

4. Omi mo pea san laiye
Benin won ko f’ aiye sile
Omi l’ ore ti ko se ‘re
Beni nwon ko fi O s’ ore

5. Ko s’ okan ninu wa t’ o pe
Gbogbo wa si ni elese
Awon t’ o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe

6. Sugbon Jesu Olugbala
Eni bi awa n’ Iwo ‘se
‘Wo ti ri ‘danwo bi awa

‘Wo si ti mo ailera wa

K’a to sun Olugbala wa

K’a to sun Olugbala wa

1. K’a to sun Olugbala wa
Fun wa n’ ibukun ale
A jewo ese wa fun O
Iwo l’o le gba wa la

2. B’ ile tile ti sududu
Okun ko le se wa mo
Iwo eniti ki sare
Nso awon enia Re

3. B’ iparun tile yi wa ka
Ti ofa nfo wa koja
Awon Angeli yi wa ka
Awa o wa l’ ailewu

4. Sugbon b’ iku ba ji wa pa
Ti ‘busun wa d’ iboji
Je k’ ile mo wa sodo Re
L’ ayo at’ Alafia

5. N’ irele awa f’ara wa
Sabe abo Re Baba
Jesu ‘Wo t’o sun bi awa
Se orun wa bi Tire

6. Emi Mimo rado bo wa
Tan ‘mole s’ okunkun wa
Tit’ awa o fi ri ojo

Imole aiyeraiye

Onigbagbo e bu sayo!


Onigbagbo e bu sayo!
1. Onigbagbo e bu sayo!
Ojo nla loni fun wa
Korun fayo korin kikan,
Kigbo atodan gberin
E ho! E yo!
Okun atodo gbogbo.

2. E jumo yo, gbogbo eda,
Laye yi ati lorun,
Ki gbogbo ohun alaaye
Nile, loke, yin Jesu
E fogo fun
Oba nla ta bi loni.

3. Gbohun yin ga, "Om'Afrika"
Eyin iran Yoruba;
Ke "Hosanna" lohun gooro
Jake jado ile wa.
Koba gbogbo,
Juba Jesu Oba wa.

4. E damuso! E damuso!
E ho ye! Ke si ma yo,
Itegun Esu fo wayi,
"Iru-omobinrin" de.
Halleluyah!
Olurapada, Oba.

5. E gbohun yin ga, Serafu,
Kerubu, leba ite;
Angeli ateniyan mimo,
Pelu gbogbo ogun orun.
E ba wa yo!
Odun idasile de.

6. Metalokan, Eni Mimo
Baba Olodumare
Emi Mimo, Olutunnu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa
'Wo nikan logo ye fun.

Ojo nla l’ ojo ti mo yan

Ojo nla l’ ojo ti mo yan

1. Ojo nla l’ ojo ti mo yan
Olugbala l’ Olorun mi;
Oye ki okan mi ma yo,
K’o si ro ihin na ka ‘le.

Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu.

2.        Ide mimo t’o s’ edidi
Eje mi f’ Eni ye ki nfe?
Jek’ orin didun kun ‘le Re
Nigba mo ban lo sin nibe.

3.        Mo ti b’ Oluwa sadehun!
Mo di Tire, On di temi,
On l’o pe mi, ti mo si je,
Mo f’ ayo jipe mimo na.

4.        Simi, okan aiduro mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Ma f’ Oluwa re sile lai,
Lodo Re n’ ire re gbe wa.

5.        ‘Wo orun t’o gbo eje mi
Y’o ma tun gbo lojojumo,
Tit’ ojo t’ emi mi y’o pin,

Ti ngo mu majemu na se.


O HAPPY DAY THAT FIXED MY CHOICE
1. O happy day, that fixed my choice,
On Thee, My Saviour and my God!
Well May this glowing heart rejoice,
And tell its raptures all abroad.

Happy day, happy day,
When Jesus washed my sins away!
He taught me how to watch and pray,
All live rejoicing ev’ry day.
Happy day, happy day,
When Jesus washed my sins away!
                 
2. Tis done, the great transaction’s done!
I am my Lord’s and He is mine:
He drew me and I followed on,
Charmed to confess the voice divine.

3. Now rest, my long-divided heart,
Fixed on this blissful centre, rest:
Nor ever from thy Lord depart,
With Him of every good possessed.

4. High heaven, that heard the solemn vow,
That vow renewed shall daily hear,
Till in life’s latest hour I bow,
And bless in death a bond so dear.

P. Doddridge.

Enikan nbe to feran wa

Enikan nbe to feran wa
Enikan nbe to feran wa
A! O fe wa!
Ife Re ju t'iyekan lo
A! O fe wa!
Ore aye nko wa sile
Boni dun, ola le koro
Sugbon Ore yi ki ntan ni
A! O fe wa!

Iye ni fun wa ba ba mo
A! O fe wa!
Ro, ba ti je ni gbese to
A! O fe wa!
Eje Re lo si fi ra wa
Nin'aginju l'O wa wa ri
O si mu wa wa sagbo Re
A! O fe wa!

Ore ododo ni Jesu
A! O fe wa!
O fe lati ma bukun wa
A! O fe wa!
Okan wa fe gbo ohun Re
Okan wa fe lati sunmo
Oun na ko si ni tan wa ke
A! O fe wa!

Oun lo je ka ridariji
A! O fe wa!
Oun o le ota wa sehin
A! O fe wa!
Oun o pese 'bukun fun wa
Ire la o ma ri titi
Oun o fi mu wa lo sogo
A! O fe wa!

B’ORUKO JESU TI DUN TO

B’ORUKO JESU TI DUN TO
1. B’oruko Jesu ti dun to,
ogo ni fun Oruko Re
o tan banuje at’ogbe
ogo ni fun oruko Re

ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa
ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa

2. O wo okan to gb’ogbe san
Ogo ni fun oruko Re
Onje ni f’okan t’ebi npa
Ogo ni fun oruko Re

3. O tan aniyan elese,
Ogo ni fun oruko Re
Ofun alare ni simi
Ogo ni fun oruko Re

4. Nje un o royin na f’elese,
Ogo ni fun oruko re
Pe mo ti ri Olugbala
Ogo ni fun oruka Re.